Irohin latodo mi! (News from me)

The inspiration for this post came from reading this blog http://irinajoyinbo.wordpress.com

My apologies to non-Yoruba speakers but you will need to be able to read yoruba or find an interpreter to understand the post below:) I have also put up pictures and a video so you have a pretty good idea of the topics of my rants:)!

O ti pe ti mo ti fe ko awon oro yii sile sugbon mi o ti setan lati se afi lehin ti mo ka 'blog' Kayode, mo ranti pe mo le ko awon oro yii ni ede ti die laarin awon to ma n ka 'blog' mi le ka. Kii sepe mo ni nkan fipamo sugbon lasiko, awon oro kan wa to dun so lede mi, ko de si oro ninu ede geesi to le mu oyin kuro ninu okuta.

Nkan sele leni ti o ya mi lenu gan.....................................................................................................................................................................hmmm e ma binu iya to ya mi o je n ko le:)

Awon ile ologe ni awon oro mi to ku wa fun

1. Ki ni idi ti awon okunrin loni ma n wo sokoto won lai so! O ma n ya mi lenu gidigidi ti mo ba n ri okunrin ti kii sepe o ya were, to wo buba daadaa, bata paapaa ma wa lese, sokoto a de wapa sugbon to ba n rin, eyan ma ripe sokoto jabo nidi re! Igba ti mo kokori sokoto bayii, mo tiju sugbon mo sofun omo sukuru yi pe, mabinu o sugbon sokoto n jabo nidi e. Oju to fi wo mi mu mi dake. Lehin yen ni mo gbo pe 'latest fashion' ni o! Won ma n pe ni 'sagging' . Oro ti mo ma n pe awon obo wonyii o se kole. Mo lo pe won l'obo sha:). Ti won ba le wo beltii ki won duro nile, ki won ma jade. Mi o sofun enikankan laaro pe mo fe wo idi ti won fi n yagbe lojojumo, mi o de fe di afoju laaro aiye mi!



2.Oro ikeji mi ni wipe kilode ti awon miran ma n wo igo dudu ti ko ba sorun kankan nita. Awon min paapaa man wo igo yi ni inu ile. Awon oyinbo to da igo sile, won se igo dudu fun awon ti ina orun le ba oju won je. Sugbon laiye isin awon odo ati awon agbalagba ma n wo igo nigbogbo igba. Won ran mi leti nipaa ojogbon kan ti n je abacha to je agbalumo obirin to fi ku. Oun na ma n wo igo yi loojojumo. Ti mo ba ri won, omo abacha mo ma n pe won.


3. Ohun iketa ti mo fe soro nipa ni awon omoge wa. Mo fe kilo kekere fun won pe ki won ma gbadun irun to olorun fun wan. Bi mo se n kilo fun yin, mo fi n kilo fun ara mi naa. Opolopo ninu wa (emi na pelu) man se gbogbo nkan lati fi je ki irun wa di ti oyibo. Nigbati olorun da wa, olorun fun wa ni irun to 'kinky', irun to lewa to de daa fun wa. Mo fe ki a ma serun wa jeje. Gbogbo awon 'chemical' ta ma n fi fo ori wa ma n jeki o baje. Arun ti awon dokita ma n pe ni 'alopecia areata' (ko ni je ti wa o) le sele lehin fifi 'chemical' yi sirun wa! To ba ti e jepe a fe fi sirun wa bi agbalagba, awon omo ti o mo n kankan ko. E je ki awon omo kekere gbadun irun won ka to ma fi 'chemical' abi 'irun oku' so mo ori ti won o! Ikilo naa ni, e le gba, abi ke ko, ki se dandan o!
Mo fi video kekere yi fun awon obi ati omo ki won wo, ko de si da yin laraya!


I enjoyed doing this and should hopefully do it on a weekly basis:)

For those of you who will crucify me for using the words chemical and kinky in my essay. I dont know what those words in yoruba are. I checked an online translator for chemical and it came up with èlò ìpìlë tí a finmúohun míràn. See why I did not include it:)

Have a great day!

Comments

  1. lol! mo gbadun 'post' yi gan! ibon die die wa ninu e sugbon o gbiyanju lopolopo...(adding a translation might help people follow through) God bless

    ReplyDelete
  2. Eni Okuns7:20 AM

    Tomi..o dabi npe mo ma ko ede lati odo re. Ku ise naa. Olorun afun e ni imo ati oye lati ko omiran......lol

    ReplyDelete
  3. Anonymous9:36 AM

    OláOlúwatómi, pèlú àwon kókó ínún òrò yíí, ‘o so ojú abe ní ìkó’. Bì àwon okùnrin se má a n gbé sòkòtò sí bèbèré ìdí kò yé mi, ojú kìí tì wón ni? Sé o rí nípa ti ìgó wíwó, won a ma se yèyé pé ‘ìgó lójú omo òdaràn’. Kò tíe tó áwon oko ìyàwó tí wón màá n wo ní ojó ìgbéyàwó won! (...smh). Nípa òrò irun àwa obìrin, tóótó lo so, ara nnkan tí ó n pa àsa oge síse wa nì yen! Mo rántí ayíé ìgba ‘sùkú’, ‘korobá’, ‘ko jú s’óko’ lol!!!
    I swear, we need a Yoruba language complaint keyboard :D This was def. fun! Let’s do it again.

    ReplyDelete
  4. Bimpe3:19 PM

    Love this Tomi, O gbiyanju ni tooto. Kare omo yoruba daada!

    ReplyDelete
  5. Ese pupo gbogbo yin ti e fi comment le lori blog me! LOL! I enjoyed reading your comments in yoruba! Thanks for the compliments

    ReplyDelete

Post a Comment

Popular posts from this blog

Bonny Island!

Death III

My Mother Tongue!