ìÿõÿöohun olóòrúùn fírífíríilé ìyàgbé*


Laarin awon anfaani to wa ni kiko yoruba nipe eyan le ko awon oro kan ti o ni ti yan loju. Toba jepe mo ko ni ede geesi ara ma ma se mi bakan, sugbon ti mo ba ko ni ede awon baba mi, ko ni jo mi loju. Oro ti mo fe ko nsin je okan ninu awon oro wonyi.
Ki leyan le ko lori oro 'ile igbonse'? Opolopo oro wa o!
Nibise mi nigbakan ti m ba fe lo lo ile igbonse mo mo pe mo ma rin nkan ti o ma je ki inu ro mi. Ni ile ise yii, omi ati ose wa nigbagbogbo. Ko de s ojo kan ti eyan ma lo sibe lai ripe omi n san bi okun. Sugbon awon eyan wa to ma n lo ile igbonse yii won de ni fi omi fo idooti won kuuro. Igba ti mo koko rii kini buruku yii mo sare fi omi san kuro. Mo ro wipe boya eyan yen sare kuro ko de farabale duro ko ri boya igbe ti lo tan. Sugbon igba to sele lera lera mo ro wipe boya obun leni naa.
Ki ni idi ti awon eyan ma n lo ile igbonse lai fi omi fo idooti won kuro? ko ma yemi o! To ba je pe ko ti e si omi, a le se **ìmúkúròìÿàtìkíkö láti gbà fun won. Sugbon ni ibi ti omi wa, eyan kan ma ***mirugbon ori!
Ati gba ti mo wa ni kekere ese ti o se dariji nile wa nipe k eyan lo ile igbonse ko ma fi omi fo daadaa. Mama mi ni eyan to fe ki gbogbo ile mo toto. Mo ranti ojo kan ti awon obi wa setan lati mu wa jade lo jeun. Ojo yi je ojo àkànÿepàtàkìötö nitoripe baba mi o feran awon ile ounje nita. Inu gbogbo wa lodun nitori ile ounje chinese ni won fe mu wa lo. Igba ti a de be, ati joko gan ti a ba bere sin gborun nkan. Mama mi ki ise eni ti oju man ti won lati bere nkan, kaikai ni won ti soro. Won bere lowo awon onise nibe, pe ki lo n run o? Se ile igbonse yin lo n run buruku yii? Oniise na wipe, o ti o, kiise ile igbonse lo n run o, boya eku kan lo ti ku ninu ile.
Haa, a ti e joko mo, ni kaikai ni awon obi mi jade kuro nibe. Mama mi sope, o dan won loju pe, ile igbonse won lo run, baba mi wiipe idi niyen ti won fi fe ka ma jeun nita. Eyan o ni mo boya omi ti won fi fo oku ni won fi n sounje ti won ta! :))
Ko si nkan to da ju ile igbonse to mo daadaa, to si l omi ati ose ki eyan fi fo owo lehin ti a ba ti lo lo.
Igbagbo mi nipe gbogbo ile igbonse ti mo ba lo a mo to pe mo le ti e sun ninu won. Mo fe ki e so fun mi itan teni lori ile igbonse ti e ti ba pade! Ma ma reti irohin lati odo yin o!


Translation
*Toilet- ìÿõÿöohun olóòrúùn fírífíríilé ìyàgbé
*Shake- Mirugbon

**Exception-ìmúkúròìÿàtìkíkö
Special-àkànÿepàtàkìötö

Comments

  1. lol, how long did it it take you to do this?

    ReplyDelete
  2. Not too long! About 30mins all told i think, stopped had to do something and came back again to continue!

    ReplyDelete
  3. O ku ise Tomi. Oluwa a lora emi e fun wa amin. Ori mi wu gidigidi lati ri ojulowo omo oodua ti o n ko ede abinibi wa daradara. Awon agba a so wipe - Ori re o kan oke.

    Nipa oro ile igbonse. Hmmmm. Emi na korira egbin lopolopo. Sugbon ibi ti oro yi ti lagbara ju ni Ile Iwe. Ni igba ti mo wa ni Ifatiti Ile-Ife, eyi ti won fi se eye fun Oloye Obafemi Awolowo; oju mi to. Eniyan miran o ti e ni lo awo ile igbonse, won a se gaa si ile. Orisirisi ni a ri o.

    Eyi lo mu mi mo pe, eranko wa ni inu awon eniyan kan. O ga.

    ReplyDelete
  4. Ayobami e ma se gan! Inu mi dun lati ka iwe to ko si mi. Eranko gan la ma pe awon ti won yagbe lorile. E ma je ki n bi,a ma gbadura pe won ma di eyan gidi laiye won:))

    ReplyDelete
  5. Tomi! Ikeji mi, O gbiyanju gan!
    Ni oro to ko sile, ati kekere ni a ma ko awon omo wa bi won ni lati lo ile igbonse ati gbogbo imototo. Ti won ba dagba won ni file mo!
    Awon to dabi eranko yi, ki n se ejo won - won ko won daa daa ni.
    Ore mi Ayobami , se o ranti nkan ti awon mi n pe ni 'shotput'. Kai! Oro wa!

    ReplyDelete
  6. Anonymous2:38 AM

    O kare! Omo l'uabi...

    ReplyDelete
  7. Amin o Tomi. A a ni dake adura rara.

    @ Toyin - beeni o mama 'Lase. Shortput kii se ajooji si awon obun ni igba naa. Emi tire ma nro wipe awon Okunrin nikan ni o ni iwa obun lowo. Sugbon iyalenu ni o je si mi ti n ba wo ibugbe awon obinrin bii Moza. Awon oorun akonilooyi ti o ma njade lagbara. Bee na ni awon obinrin kan a ma binu pe elegbe won miran nba ile igbonse jee. Eyi ni wipe - tako tabo la da Eranko ;)

    ReplyDelete
  8. @Ayobami & Ty - e si ma ko orin yin 'great ife' nigbogbo igba, kai:))
    @Chinny- you are supposed to write in Yoruba!
    @Anonymous- ese puupo!

    ReplyDelete
  9. we both know that would be a stretch!!! :D But I will attempt a 'ku se'... happy?

    ReplyDelete

Post a Comment

Popular posts from this blog

Death III

Death 5

My Mother Tongue!