Sise Ville!*

Enyin eyan mi, mo ki yin 'eku osu titun'. Ba wo ni nkan gbogbo? Ironu mi nipe gbogbo e n lo daadaa!

Irohin mi leni ni nipa ajoyo ti mo lo ni ose to koja. Ilu oyinbo ni sise yi ti sele, sugbon igba ti mo wole si ibi ti won se ajoyo yii, o dabi pe mo ti f ese kan pada si ilu mi Nigeria. Paapaa Ile yoruba.

L'akoko, gbogbo awon ti o wa si sise yii wo aso yoruba. Gele orisirisi lo wa, e de mo awon eyan mi, gele onikaluku gaa to orun. Gele orisiris, Gele skentele, gele madam Kofo mbe nibe pelu. Oju mi kan fo kaakiri yara ti a wa. Awon okunrin naa de fila si.

Ijo nko, won ma jo. Lati nkan bi ago mejo titi di ago mejila oru, awon eyan mi n komole, kodide:), Awon akonrin sise gidigan o, ilu na n dun daadaa. Oran mileti sise kan ti mo lo nigbati mo wa lomo kekere it IK Dairo kanrin nibe. Mi o le gbagbe sise yen lai lai. Eni ti n korin ni ohun to da gan, O de n kanrin oriki awon alejo to wa. Mi o lo jo o, ki won to le mi lo, pe erin n jo lori ile wan:)

Nkan soso ti sise yii ranmileti nipa awon Yoruba nipe a feran nkan to da gan! Ni ede Oyinbo a ni 'a zest for life'. E ma gbadun awon 'piksho' ati 'video' ti mo ya nibe!





*Sise Ville- Entertainment Ville!

Comments

Popular posts from this blog

Bonny Island!

Death III

My Mother Tongue!